nowayobloggers

Bi aba nsoro nipa EWA, ILA KIKO je okan LARA awon oun eso yoruba ni atijo ati pe, bi a ba wo oju opolopo awon Omo yoruba ni aye atijo a O ri ILA loju won. Ogooro awon eyan ni O tun mo oun ti ila tun sise fun ati idi ti a fi nko ila. Idi ti a si fi nko ila pin si oniruru ona sugbon a o se alaye lori ona MEJI. ALAYE AKOKO: awon eniyan iwo orun nibi ti asa yi ti bere ri pe yio bukun EWA ara won nipa sise bee. Bi a ba wo oju elomiran ninu awon okunrin tabi obinrin ti O ko ila,a O ri wipe ila naa Dara pupo loju opolopo won. Dajudaju idi niyii ti a fi le ka ila kiko kun ara ASA lati le bu si EWA. Bi a ko ba Tori isu j’epo, a O tori epo je su. Bi a ba si wo finnifinni a ori pe ila won yi yato si ara won lati ilu si ilu tabi lati agbegbe si agbegbe. Awon EKITI ni nbu meta-meta ti O gbooro,abi eyo kan soso ti O gbooro, tabi meta ooro Lori meta ibu ti O ogbooro. Awon EGBA ni nko meta-meta ti ko gun ti kosi gbooro. Awon IJEBU Na nko meta-meta tabi meta loke, meta ni isale re. Awon OWU maa n bu abaja, be si ni won ma n bu keke. Pupo ninu awon ife kii kolaa sugbon awon di e ninu won ma n bu meta-meta nigba Miran. Awon IJESA nko mefa. ONDO nko Pele oju kookan ti o inrin ti O si jinle. Awon igbomina nko meta-meta. Awon iyagba nko meta-meta ti O fere papo leba enu won. Nigba ti awon OYO nko orisirisi abaja, Pele ati ture. Won a tu mo ko agbaja meta-meta, merin-merin, meje-meje, agbaja akopo meta l’ori merin, keke tabi gombo papo.   ALAYE KEJI: Ni to ri ogu ati ote ti o po nigba laelae laarin awon ilu si ilu, ati eleya meya eyi ti o mu ki awon Omo ma s’onun lairo tele. Nigba ti awon alagbara nko Omo awon ti k’olagbara ta. Bi won ti nko Omo won bee ni won nko aya won paapaa. Bee ni opo gende nnu, ti won nfi won se awairi,  bi won ti nko won ni won ta won leru. Eyi tu mu ki awon agbalagba ronu wipe oye ki nkan wa gege bi AMIN eyi ti won yi o fi ma mon arawon. Eyi ti won yio si file so leekana ilu tabi agbole ti eniyan kan ti wa ni kete ti won Bari. Ogbon ILA KIKO yi ki se ti gbogbo orile ede yi lati bere bi kose oun ti awon eniyan orile ede yi jogun ba lati iwo orun nibi ti ASA Na ti koko bere.   Apejuwe awon ILA NA NIWONYI: 
Abaja: eyi ni awon ILA meta ti a fa nibu L’ori arawon,tabi mefa ti a to ni meta-meta nibu bakanan.

Abaja merin: iyato ti nbe larin mejeji ni wipe Abu ti akoko ni meta-meta sugbon abu eleyi ni merin-merin.

Pele Ijesa: meta looro ni.

Abaja Ijesa: merin n’bu ni.

Pele ati Abaja ekiti: awon wonyi yato si awon pele ati abaja ti a ti se alaye re nitoripe won gbooro pupo ju ti isaju lo.

Abaja olowu: ILA meta loro ati meta IBU ni isale won ni Abaja olowu.

keke olowu eleyi yato si keke ti akoko Siso ni keke ti olowu bibu ni ti akoko.

Ture: ILA meta kekeeke looro ati meta Miran tibo gun ju meta isaju lo l’anpe nu Ture. 

Pele ijebu: ILA meta ti O gun die.

Pele ife: ILA meta ooro. Ati bebelo.

SHARE

Comments

    NO COMMENT

Leave Your Comment

Sign up to continue.

Your email address will not be published. Required fields are marked.

Already a member?? Login