nowayobloggers

‘Ewa je ohun ti alepe ni ohun ti O un se okufa ki nkan wuni,Kia feran tabi nifen nkan bakana ni otun tumon si ki nkan joju ngbese ko si ma Dani loru. Nigbati ASA je oun iwuri ti ihuwasi ti isedale tabi oun ti idile. bi ajogun ba tabi bi won tifilele nigba iwase lati le mafi se ayeye iranti. Nitorina alesope EWA ASA YORUBA je oun ti on’dani lorun ninu ise,ihuwasi ati sise eto ni ile yoruba ni ona ooto ti O to. Bakanan lara awon asa ti yoruba si feran julo ni asa imototo eyi ti ara titunse si je okan pataki ninu won ninu eyi ti ati ri ewa IRUN SISE. IYATO TI O WA LARIN-IN EWA ati ASA. EWA Je oun okunfa adani loru ti mu ki eniyan ma feran nkan. Nigba ti ASA si je oun iwa tabi oun isedale, isedalu tabi ti idile ti a fi pinle ti o si ti fidi mule.  EWA ASA YORUBA LORI IRUN SISE. Awon abanise irun ni aunpe ni ONIDIRI. Nigba ti asi ma nkiwon wipe OJUGOOROOO OH.
IRUN: IPA TI IRUN ORI NKO LARA EWA OMO ENIYAN ATI OWO TI IRUN UN FUNNI. Nitori yoruba gbagbo pe Irinisi ni se ni lojo. Iru sise je oun ti O n buyi kun eniyan ati wipe otun je ona kan gboogi ti yoruba gbagbo wipe ama n fi n saponle eleda eni nipa fifi tun eleda eni se gege bi yoruba ti nigbagbo pe ori eni ni ngbeni. Irun sise se Pataki   fun awon obinrin laye atijo Papa julo fun awon obinrin ti O ti wole oko tabi to sese Fe wole oko, Nitoripe irun sise nbe Lara awon oun ti O ma nse agbaso tabi sapejuwe Iru itoju ti aya nla koja lode oko re. Osi tun un se afihan oun ti tokotaya nfe nipa fifi ara tabi oju bara eni soro, (ERE LOKO LAYA) ti a ban so nipa imura ile oko tabi niti gdajumo l’aye atijo irun sise je okan Pataki lara awon oun iwuri ti a o le f’owo ro seyin. IRUN SISE FUN AWON OBINRIN NILE YORUBA. Gege bi ati mon pe irun sise se Pataki fun awon obinrin ni ile yoruba. Ipa meji ni irun sise pin si nigba ti a si ni aramonda oniruru ara ti a le fiwon da. IPA AKOKO: IRUN DIDI, IPA EKEJI: IRUN KIKO. Iyato ti O wa larin irun Didi ati kiko ni wipe owu tabi roba ni won fi nko run ati wipe aki korun lai mon lo asomo (asomo pondandan).ati wipe yoruba gbagbo pe kiko irun ma nje ki irun tete gun.  IRUN DIDI: IRUN DiDi si je abamole tabi adadi irun nikan lai ni asomo bakanan alee lo asomo ti a b’afe sugbon (asomo O pon dandan) Fun irun Didi.IPA MEJI NI IRUN DIDI PIN SI: IPA KINI: Iru biba, Irun biba je irun ti a ma fi n gboriro ki a to pinu tabi ki ato Raye lati lo f’irun wa dara ti O joju ngbese. IPAKEJI: irun aladitan,eyi ni irun ti atise pari pelu oun elo iserun oniruru.(awa fun ra tika alarawa le barun le ara wa Lori tabi kani ki orewa b’awa ba Sugbon awon onidiri ni O ma nse irun asetan ki O le gun rege ki O tun le joju ngbese nitori pe ise ti won ko ni)  Opolopo oniruru irun Didi ati kiko si ni nbe. AWON IRUN TI NBE: ONILE GOGORO ALAKABA, IPAKO ELEDE, FILA OLOPA,SUKU,SUKU ALADIMOLE,EKO-BRIGDE, ROUNDABOUT, PATEWO,AGOGO,OJONPETI, ALL BACK, KOJUSOKO,KEYINSOKO,ILEKEDI,IKOTO,IYAWO OSINGIN,AJANLOSO,ADE OBA,OGUNPARI,AJANKOLOKOLO,ONALA,AKABA MEJI,KULIKULI,PINEAPPLE, MOWANPA,PATEWO,KOROBA,PANUMO,PAKUNPO,EWE OGEDE ati bebelo.

string(59) "http://www.nowayofotohome.com/uploads/1479572452_yoruba.jpg" string(61) "http://www.nowayofotohome.com/uploads/1479572452_yoruba-1.jpg" string(61) "http://www.nowayofotohome.com/uploads/1479572452_yoruba-2.jpg" string(61) "http://www.nowayofotohome.com/uploads/1479572452_yoruba-4.jpg"
SHARE

Comments

    NO COMMENT

Leave Your Comment

Sign up to continue.

Your email address will not be published. Required fields are marked.

Already a member?? Login