nowayobloggers

SATIDE ojo kokanlelogun, osuu yii lopolopo awon omo Yoruba ti won n gbe orile-ede Italy peju-pese sibi ayeye ajodun odun kin-in-ni idasile egbe omoô Yoruba, Emilia Romagna niluu Italy.

Lara awon eto alarinrin ti won fi da awon eeyan laraya ni ijo ibile, asa lorisiirisii (bii ikini lede Yoruba, asa igbeyawo, asa isomoloruko nilana ibile ati bee bee lo) lati fi ran awon to pe die ti won ti kuro nile atawon omo ti won bi siluu oyinbo leti asa ati ise ile Yoruba.
Ninu oro ikini kaabo aare egbe naa, Dokita Olumide Okunuga, o ki gbogbo awon omo egbe fun akitiyan won lati fi idi egbe ohun mule ati lati ma je ki asa ati ise ile Yoruba, paapaa ede parun laarin awon omo won.
O ni, “Lara awon idi pataki ta a fi da egbe yii sile ni lati ri i pe ifeô ati irepo joba laarin gbogbo awa omo ile kaaro-o-o-jiire lorile-ede Italy ati lati maa sun mo ara wa fun iranlowo te niko okan wa le nilo niluu ajoji ta a wa yii.
“Mo si tun n fi asiko yii ro gbogbo awa omo egbe pe ka tubo mura si gbogbo ona ti egbe omo Yoruba nile Italy yoo se di igi aloye ti yoo si maa se anfaani fun gbogbo omo egbe.”
Lara awon alejo pataki ti won peju-pese sibi ayeye ohun lasoju ijoba agbegbe Modena, Arabinrin Francesca Maletti, aare egbe omo Yoruba ni agbegbe Firenze, Ogbeni Adeyeômi Adebayo, onisowo pataki kan niluu Italy to tun se alaga ijokoo ojo ohun, Ogbeni Festus Akin Akingboju.
Ninu oro asoju ijoba agbegbe Modena, Arabinrin Francesca Maletti, o gbe osuba fun awon asaaju egbe omo Yoruba fun akitiyan won lati ma je ki asa ati ise won parun, o ro woôn lati tubo te siwaju lati maa se orisiirisii eto nigba gbogbo ti yoo maa ran awon eeyan won leti pe ile labo isinmi oko.
Eni ti won fi se mama ojo naa ni Alaaja Iyabode Garuba ti opolopo awon eeyan tun mo si Alaaja Bologna, Arabinrin Aderonke Ebiesuwa ni alaga obinrin. Bakan naa lawon omo egbe Yoruba lati agbegbe Parma peôlu alaga won, Ogbeni Femi Ajibola naa ko gbeyin.
Ninu oro idupe alaga igbimo to seto ayeye ohun, Ogbeni Bolaji Amodu, o dupe lowo gbogbo awon omo egbe fun ifowo-sowo-po won.

SHARE

Comments

    NO COMMENT

Leave Your Comment

Sign up to continue.

Your email address will not be published. Required fields are marked.

Already a member?? Login